Native Bible

Deuteronomy 21:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

kí o sì mú aṣọ tí ó wọ̀ nígbà tí ó di ìgbèkùn sí ẹ̀gbẹ́ kan. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ń gbé ilé rẹ tí ó sì ti ṣọ̀fọ̀ baba àti ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan, nígbà náà ni o lè tọ̀ ọ́ lọ kí o sì ṣe ọkọ rẹ̀ kí ó jẹ́ aya rẹ.

Deuteronomy 21:13 in English

Deuteronomy 21:13 · Berean Standard Bible

and put aside the clothing of her captivity. After she has lived in your house a full month and mourned her father and mother, you may have relations with her and be her husband, and she shall be your wife.

Context

11tí o sì rí obìnrin tí ó dára lára àwọn ìgbèkùn, tí o sì ní ìfẹ́ sí i, o lè mu u gẹ́gẹ́ bí aya à rẹ. 12Mú u wá sí ilé e rẹ kí o sì jẹ́ kí ó fá irun orí rẹ̀, gé èékánná an rẹ̀, 13kí o sì mú aṣọ tí ó wọ̀ nígbà tí ó di ìgbèkùn sí ẹ̀gbẹ́ kan. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ń gbé ilé rẹ tí ó sì ti ṣọ̀fọ̀ baba àti ìyá rẹ̀ fún odidi oṣù kan, nígbà náà ni o lè tọ̀ ọ́ lọ kí o sì ṣe ọkọ rẹ̀ kí ó jẹ́ aya rẹ. 14Bí inú rẹ̀ kò bá sì dùn sí i, jẹ́ kí ó lọ sí ibikíbi tí ó bá fẹ́. O kò gbọdọ̀ tà á tàbí lò ó bí ẹrú, lẹ́yìn ìgbà tí o ti dójútì í. 15Bí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tí ó sì fẹ́ ọ̀kan ṣùgbọ́n tí kò fẹ́ èkejì, tí àwọn méjèèjì sì bí àwọn ọmọkùnrin fún un ṣùgbọ́n tí àkọ́bí jẹ́ ọmọ ìyàwó rẹ̀ tí kò fẹ́ràn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.