Native Bible

Daniel 6:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Mo gbé àṣẹ kan jáde wí pé, ní gbogbo agbègbè ìjọba mi, gbogbo ènìyàn gbọdọ̀ bẹ̀rù, kí wọn kí ó sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Daniẹli. “Nítorí òun ni Ọlọ́run alààyè. Ó sì wà títí ayé; ìjọba rẹ̀ kò le è parun, ìjọba rẹ̀ kò ní ìpẹ̀kun.

Daniel 6:26 in English

Daniel 6:26 · Berean Standard Bible

I hereby decree that in every part of my kingdom, men are to tremble in fear before the God of Daniel: For He is the living God, and He endures forever; His kingdom will never be destroyed, and His dominion will never end.

Context

24Ọba pàṣẹ pé, kí a mú àwọn alátakò Daniẹli wá, kí a jù wọ́n sí inú ihò kìnnìún, pẹ̀lú ìyàwó àti àwọn ọmọ wọn. Kí wọn tó dé ìsàlẹ̀ ihò, kìnnìún lágbára lórí i wọn, wọ́n sì fọ́ gbogbo egungun wọn. 25Nígbà náà ni Dariusi ọba kọ̀wé sí gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè, àti gbogbo jákèjádò ilẹ̀ náà: “Kí ìre yín máa pọ̀ sí i! 26“Mo gbé àṣẹ kan jáde wí pé, ní gbogbo agbègbè ìjọba mi, gbogbo ènìyàn gbọdọ̀ bẹ̀rù, kí wọn kí ó sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Daniẹli. “Nítorí òun ni Ọlọ́run alààyè. Ó sì wà títí ayé; ìjọba rẹ̀ kò le è parun, ìjọba rẹ̀ kò ní ìpẹ̀kun. 27Ó ń yọ ni, ó sì ń gbani là; ó ń ṣe iṣẹ́ àmì àti ìyanu ní ọ̀run àti ní ayé. Òun ló gba Daniẹli là kúrò lọ́wọ́ agbára kìnnìún.” 28Daniẹli sì ṣe rere ní àkókò ìjọba Dariusi àti àkókò ìjọba Kirusi ti Persia.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.