Daniẹli 6:27
Daniel 6:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó ń yọ ni, ó sì ń gbani là; ó ń ṣe iṣẹ́ àmì àti ìyanu ní ọ̀run àti ní ayé. Òun ló gba Daniẹli là kúrò lọ́wọ́ agbára kìnnìún.”
Daniel 6:27 in English
Daniel 6:27 · Berean Standard Bible
He delivers and rescues; He performs signs and wonders in the heavens and on the earth, for He has rescued Daniel from the power of the lions.”
Context
25Nígbà náà ni Dariusi ọba kọ̀wé sí gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè, àti gbogbo jákèjádò ilẹ̀ náà:
“Kí ìre yín máa pọ̀ sí i! 26“Mo gbé àṣẹ kan jáde wí pé, ní gbogbo agbègbè ìjọba mi, gbogbo ènìyàn gbọdọ̀ bẹ̀rù, kí wọn kí ó sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Daniẹli.
“Nítorí òun ni Ọlọ́run alààyè.
Ó sì wà títí ayé;
ìjọba rẹ̀ kò le è parun,
ìjọba rẹ̀ kò ní ìpẹ̀kun. 27Ó ń yọ ni, ó sì ń gbani là;
ó ń ṣe iṣẹ́ àmì àti ìyanu
ní ọ̀run àti ní ayé.
Òun ló gba Daniẹli là
kúrò lọ́wọ́ agbára kìnnìún.” 28Daniẹli sì ṣe rere ní àkókò ìjọba Dariusi àti àkókò ìjọba Kirusi ti Persia.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.