Daniẹli 12:3
Daniel 12:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé.
Daniel 12:3 in English
Daniel 12:3 · Berean Standard Bible
Then the wise will shine like the brightness of the heavens,* and those who lead many to righteousness will shine like the stars forever and ever.*
Context
1“Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà. 2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun. 3Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé. 4Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.” 5Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.