Daniẹli 12:1
Daniel 12:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà.
Daniel 12:1 in English
Daniel 12:1 · Berean Standard Bible
“At that time Michael, the great prince who stands watch over your people, will rise up. There will be a time of distress, the likes of which will not have occurred from the beginning of nations until that time. But at that time your people—everyone whose name is found written in the book—will be delivered.
Context
1“Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà. 2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun. 3Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.