Daniẹli 12:2
Daniel 12:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun.
Daniel 12:2 in English
Daniel 12:2 · Berean Standard Bible
And many who sleep in the dust of the earth will awake, some to everlasting life, but others to shame and everlasting contempt.*
Context
1“Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà. 2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun. 3Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé. 4Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.