Native Bible

Daniel 12:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè.

Daniel 12:5 in English

Daniel 12:5 · Berean Standard Bible

Then I, Daniel, looked and saw two others standing there, one on this bank of the river and one on the opposite bank.

Context

3Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé. 4Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.” 5Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè. 6Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?” 7Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátápátá, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.