Kolose 3:16
Colossians 3:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́.
Colossians 3:16 in English
Colossians 3:16 · Berean Standard Bible
Let the word of Christ richly dwell within you as you teach and admonish one another with all wisdom, and as you sing psalms, hymns, and spiritual songs with gratitude in your hearts to God.
Context
14Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé. 15Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́. 16Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́. 17Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jesu Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Baba nípasẹ̀ rẹ̀. 18Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.