Native Bible

Colossians 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́.

Colossians 3:15 in English

Colossians 3:15 · Berean Standard Bible

Let the peace of Christ rule in your hearts, for to this you were called as members of one body. And be thankful.

Context

13Ẹ máa fi ara dà á fún ara yín, ẹ sì máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kristi ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú. 14Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé. 15Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́. 16Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́. 17Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jesu Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Baba nípasẹ̀ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.