Kolose 3:14
Colossians 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé.
Colossians 3:14 in English
Colossians 3:14 · Berean Standard Bible
And over all these virtues put on love, which is the bond of perfect unity.
Context
12Nítorí náà, bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, ẹni mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìṣoore, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù àti sùúrù. 13Ẹ máa fi ara dà á fún ara yín, ẹ sì máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kristi ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú. 14Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé. 15Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́. 16Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.