Native Bible

Colossians 3:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa.

Colossians 3:18 in English

Colossians 3:18 · Berean Standard Bible

Wives, submit to your husbands, as is fitting in the Lord.

Context

16Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́ ọ, kí ẹ sì máa gba ara yín níyànjú nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin sí Ọlọ́run ní ọkàn ọpẹ́. 17Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jesu Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Baba nípasẹ̀ rẹ̀. 18Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa. 19Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fẹ́ràn àwọn aya yín, ẹ má sì ṣe korò sí wọn. 20Ẹ̀yin ọmọ ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.