Native Bible

Amos 8:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa Olódùmarè wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹmpili yóò yí padà sí ohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!”

Amos 8:3 in English

Amos 8:3 · Berean Standard Bible

“In that day,” declares the Lord GOD, “the songs * of the temple * will turn to wailing. Many will be the corpses, strewn in silence everywhere!”

Context

1Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mi: agbọ̀n èso pípọ́n. 2Ó béèrè pé, “Amosi kí ni ìwọ rí.” Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.” Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Israẹli; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.” 3Olúwa Olódùmarè wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹmpili yóò yí padà sí ohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!” 4Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba, tí ẹ sì ń sọ tálákà di ilẹ̀. 5Tí ẹ ń wí pé, “Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí kí àwa bá à lè ta ọkà kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin kí àwa bá à le ta jéró?” Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á kí a sì fi òsùwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.