Amosi 8:4
Amos 8:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba, tí ẹ sì ń sọ tálákà di ilẹ̀.
Amos 8:4 in English
Amos 8:4 · Berean Standard Bible
Hear this, you who trample the needy, who do away with the poor of the land,
Context
2Ó béèrè pé, “Amosi kí ni ìwọ rí.”
Mo sì dáhùn pé, “Agbọ̀n èso pípọ́n.”
Nígbà náà ni Olúwa wí fún mi pé, “Àsìkò náà pọ́n tó fún àwọn ènìyàn mi Israẹli; Èmi kì yóò dá wọn sí mọ́.” 3Olúwa Olódùmarè wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn orin tẹmpili yóò yí padà sí ohùn réré ẹkún. Ọ̀pọ̀, àní ọ̀pọ̀ ara òkú ni yóò wà ni ibi gbogbo! Àní ni ìdákẹ́ jẹ́ẹ́!” 4Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba,
tí ẹ sì ń sọ tálákà di ilẹ̀. 5Tí ẹ ń wí pé,
“Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò parí
kí àwa bá à lè ta ọkà
kí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópin
kí àwa bá à le ta jéró?”
Kí a sì dín ìwọ̀n wa kù
kí a gbéraga lórí iye tí a ó tà á
kí a sì fi òsùwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ, 6kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn tálákà,
kí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìní,
kí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.