Native Bible

Amos 6:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa Olódùmarè ti búra fúnra rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé: “Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀, Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.”

Amos 6:8 in English

Amos 6:8 · Berean Standard Bible

The Lord GOD has sworn by Himself—the LORD, the God of Hosts, has declared: “I abhor Jacob’s pride and detest his citadels, so I will deliver up the city and everything in it.”

Context

6Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro. 7Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò. 8Olúwa Olódùmarè ti búra fúnra rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé: “Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀, Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.” 9Bí ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú. 10Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ Olúwa.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.