Native Bible

Amos 6:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò.

Amos 6:7 in English

Amos 6:7 · Berean Standard Bible

Therefore, you will now go into exile as the first of the captives, and your feasting and lounging will come to an end.

Context

5Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin. 6Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro. 7Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò. 8Olúwa Olódùmarè ti búra fúnra rẹ̀, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé: “Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀, Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.” 9Bí ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.