Native Bible

Amos 4:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nítorí náà, èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí i yín, Israẹli, àti nítorí tí èmi ó ṣe èyí sí i yín, ẹ múra láti pàdé Ọlọ́run yín, ẹ̀yin Israẹli.”

Amos 4:12 in English

Amos 4:12 · Berean Standard Bible

“Therefore, that is what I will do to you, O Israel, and since I will do this to you, prepare to meet your God, O Israel!

Context

10“Mo rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí i yín bí mo ti ṣe sí Ejibiti. Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín. Pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí a kó ní ìgbèkùn. Mo kún imú yín fún òórùn ibùdó yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí. 11“Mo ti bì ṣubú nínú yín, bí Ọlọ́run ti bi Sodomu àti Gomorra ṣubú ẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fa yọ kúrò nínú iná, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí. 12“Nítorí náà, èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí i yín, Israẹli, àti nítorí tí èmi ó ṣe èyí sí i yín, ẹ múra láti pàdé Ọlọ́run yín, ẹ̀yin Israẹli.” 13Ẹni tí ó dá àwọn òkè tí ó dá afẹ́fẹ́ tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn, ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùn tí ó sì tẹ ibi gíga ayé. Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.