Native Bible

Amos 4:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Mo rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí i yín bí mo ti ṣe sí Ejibiti. Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín. Pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí a kó ní ìgbèkùn. Mo kún imú yín fún òórùn ibùdó yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí.

Amos 4:10 in English

Amos 4:10 · Berean Standard Bible

“I sent plagues among you like those of Egypt; I killed your young men with the sword, along with your captured horses. I filled your nostrils with the stench of your camp, yet you did not return to Me,” declares the LORD.

Context

8Àwọn ènìyàn ń rìn láti ìlú kan sí ìlú mìíràn fún omi wọn kò rí mu tẹ́ wọn lọ́rùn, síbẹ̀ ẹ̀yin kò padà sí ọ̀dọ̀ mi,” ni Olúwa wí. 9“Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo kọlu ọgbà àti ọgbà àjàrà yín mo fi ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù lù wọ́n. Eṣú sì jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi olifi yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí. 10“Mo rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí i yín bí mo ti ṣe sí Ejibiti. Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín. Pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí a kó ní ìgbèkùn. Mo kún imú yín fún òórùn ibùdó yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí. 11“Mo ti bì ṣubú nínú yín, bí Ọlọ́run ti bi Sodomu àti Gomorra ṣubú ẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fa yọ kúrò nínú iná, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí. 12“Nítorí náà, èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí i yín, Israẹli, àti nítorí tí èmi ó ṣe èyí sí i yín, ẹ múra láti pàdé Ọlọ́run yín, ẹ̀yin Israẹli.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.