Native Bible

Amos 4:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo kọlu ọgbà àti ọgbà àjàrà yín mo fi ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù lù wọ́n. Eṣú sì jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi olifi yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí.

Amos 4:9 in English

Amos 4:9 · Berean Standard Bible

“I struck you with blight and mildew in your growing gardens and vineyards; the locust devoured your fig and olive trees, yet you did not return to Me,” declares the LORD.

Context

7“Àti pẹ̀lú mo mú òjò dúró nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹ́ta. Mo rán òjò sí ibùgbé kan ṣùgbọ́n kò rọ̀ sí ìlú mìíràn. Oko kan ní òjò; àwọn mìíràn kò ní ó sì gbẹ. 8Àwọn ènìyàn ń rìn láti ìlú kan sí ìlú mìíràn fún omi wọn kò rí mu tẹ́ wọn lọ́rùn, síbẹ̀ ẹ̀yin kò padà sí ọ̀dọ̀ mi,” ni Olúwa wí. 9“Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo kọlu ọgbà àti ọgbà àjàrà yín mo fi ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù lù wọ́n. Eṣú sì jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi olifi yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí. 10“Mo rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí i yín bí mo ti ṣe sí Ejibiti. Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín. Pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí a kó ní ìgbèkùn. Mo kún imú yín fún òórùn ibùdó yín, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí. 11“Mo ti bì ṣubú nínú yín, bí Ọlọ́run ti bi Sodomu àti Gomorra ṣubú ẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fa yọ kúrò nínú iná, síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.