Amosi 2:12
Amos 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Nasiri ní ọtí mu e sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀.
Amos 2:12 in English
Amos 2:12 · Berean Standard Bible
“But you made the Nazirites drink wine and commanded the prophets not to prophesy.
Context
10Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún
láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín. 11“Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yín
àti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Nasiri
èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Israẹli?”
ni Olúwa wí. 12“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Nasiri ní ọtí mu
e sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀. 13“Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀
bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀. 14Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọ
alágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀
jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.