Amosi 2:10
Amos 2:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín.
Amos 2:10 in English
Amos 2:10 · Berean Standard Bible
And I brought you up from the land of Egypt and led you forty years in the wilderness, that you might take possession of the land of the Amorite.
Context
8Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bàá a pẹpẹ,
lórí aṣọ tí wọ́n fi jẹ́ ẹ̀jẹ́
ní ilé òrìṣà wọn
wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtánràn. 9“Mo pa àwọn ará Amori run níwájú wọn
gíga ẹni tí ó dàbí igi kedari.
Òun sì le koko bí igi óákù
mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá
àti egbò rẹ̀ láti ìsàlẹ̀ wá. 10Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún
láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín. 11“Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yín
àti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Nasiri
èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Israẹli?”
ni Olúwa wí. 12“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Nasiri ní ọtí mu
e sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.