Ìṣe àwọn Aposteli 8:5
Acts 8:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn.
Acts 8:5 in English
Acts 8:5 · Berean Standard Bible
Philip went down to a city in Samaria and proclaimed the Christ to them.
Context
3Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú. 4Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo ń wàásù ọ̀rọ̀ náà. 5Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn. 6Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ́, tí wọn sì rí iṣẹ́ àmì tí Filipi ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkàn kan fiyèsí ohun tí ó ń sọ. 7Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.