Ìṣe àwọn Aposteli 8:7
Acts 8:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá.
Acts 8:7 in English
Acts 8:7 · Berean Standard Bible
With loud shrieks, unclean spirits came out of many who were possessed, and many of the paralyzed and lame were healed.
Context
5Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn. 6Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ́, tí wọn sì rí iṣẹ́ àmì tí Filipi ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkàn kan fiyèsí ohun tí ó ń sọ. 7Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá. 8Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà. 9Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Simoni, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaria. Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.