Ìṣe àwọn Aposteli 8:3
Acts 8:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.
Acts 8:3 in English
Acts 8:3 · Berean Standard Bible
But Saul began to destroy the church. Going from house to house, he dragged off men and women and put them in prison.
Context
1Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀. 2(1) Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli. (2) Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Stefanu lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀. 3Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú. 4Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo ń wàásù ọ̀rọ̀ náà. 5Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.