Native Bible

Acts 7:42 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé: “ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli?

Acts 7:42 in English

Acts 7:42 · Berean Standard Bible

But God turned away from them and gave them over to the worship of the host of heaven, as it is written in the book of the prophets: ‘Did you bring Me sacrifices and offerings forty years in the wilderness, O house of Israel?

Context

40Wọ́n wí fún Aaroni pé, ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ́nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mose yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’ 41Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rú ẹbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. 42Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé: “ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli? 43Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki, àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín, àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n. Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’ 44“Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijù. Èyí tí a ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mose sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó ti rí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.