Native Bible

Acts 7:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n wí fún Aaroni pé, ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ́nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mose yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’

Acts 7:40 in English

Acts 7:40 · Berean Standard Bible

They said to Aaron, ‘Make us gods who will go before us! As for this Moses who led us out of the land of Egypt, we do not know what has happened to him.’*

Context

38Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú angẹli náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa. 39“Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Ejibiti. 40Wọ́n wí fún Aaroni pé, ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ́nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mose yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’ 41Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rú ẹbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. 42Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé: “ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.