Native Bible

Acts 7:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki, àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín, àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n. Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’

Acts 7:43 in English

Acts 7:43 · Berean Standard Bible

You have taken along the tabernacle of Molech and the star of your god Rephan, the idols you made to worship. Therefore I will send you into exile beyond Babylon.’*

Context

41Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rú ẹbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. 42Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé: “ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli? 43Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki, àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín, àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n. Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’ 44“Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijù. Èyí tí a ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mose sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó ti rí. 45Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Joṣua wá sí ilẹ̀ ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókò Dafidi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.