Native Bible

Acts 3:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátápátá kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’

Acts 3:23 in English

Acts 3:23 · Berean Standard Bible

Everyone who does not listen to Him will be completely cut off from among his people.*’

Context

21Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti ṣẹ̀. 22Mose wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín. 23Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátápátá kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ 24“Àní, gbogbo àwọn wòlíì láti Samuẹli wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lé e, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, wọn sọ ti ọjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú. 25Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì, àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti bá àwọn baba yín dá nígbà tí ó wí fún Abrahamu pé, ‘Láti ipasẹ̀ irú àwọn ọmọ rẹ̀ ni a ó ti bùkún fún gbogbo ìdílé ayé.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.