Native Bible

Acts 3:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Àní, gbogbo àwọn wòlíì láti Samuẹli wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lé e, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, wọn sọ ti ọjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú.

Acts 3:24 in English

Acts 3:24 · Berean Standard Bible

Indeed, all the prophets from Samuel on, as many as have spoken, have proclaimed these days.

Context

22Mose wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín. 23Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátápátá kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ 24“Àní, gbogbo àwọn wòlíì láti Samuẹli wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lé e, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, wọn sọ ti ọjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú. 25Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì, àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti bá àwọn baba yín dá nígbà tí ó wí fún Abrahamu pé, ‘Láti ipasẹ̀ irú àwọn ọmọ rẹ̀ ni a ó ti bùkún fún gbogbo ìdílé ayé.’ 26Nígbà ti Ọlọ́run jí Jesu Ọmọ rẹ̀ dìde, ó kọ́ rán an sí i yín láti bùkún fún un yín, nípa yíyí olúkúlùkù yín padà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.