Ìṣe àwọn Aposteli 3:21
Acts 3:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti ṣẹ̀.
Acts 3:21 in English
Acts 3:21 · Berean Standard Bible
Heaven must take Him in until the time comes for the restoration of all things, which God announced long ago through His holy prophets.
Context
19Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, 20àti kí ó ba à lè rán Kristi tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jesu. 21Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti ṣẹ̀. 22Mose wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín. 23Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátápátá kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.