Native Bible

Acts 3:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àti kí ó ba à lè rán Kristi tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jesu.

Acts 3:20 in English

Acts 3:20 · Berean Standard Bible

that times of refreshing may come from the presence of the Lord, and that He may send Jesus, the Christ, who has been appointed for you.

Context

18Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti ṣe ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kristi rẹ̀ yóò jìyà. 19Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, 20àti kí ó ba à lè rán Kristi tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jesu. 21Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti ṣẹ̀. 22Mose wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.