Ìṣe àwọn Aposteli 23:24
Acts 23:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wí pé, kí wọn pèsè ẹṣin, kí wọ́n gbé Paulu gùn ún; kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Feliksi baálẹ̀ ní àlàáfíà.”
Acts 23:24 in English
Acts 23:24 · Berean Standard Bible
Provide mounts for Paul to take him safely to Governor Felix.”
Context
22Nígbà náà ni olórí ogun fi ọmọ náà sílẹ̀ láti lọ, ó sí kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe wí fún ẹnìkan pé, ìwọ fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.” 23Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ sí Kesarea, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹta òru. 24Ó sì wí pé, kí wọn pèsè ẹṣin, kí wọ́n gbé Paulu gùn ún; kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Feliksi baálẹ̀ ní àlàáfíà.” 25Ó sì kọ ìwé kan báyìí pé, 26Kilaudiu Lisia,
sí Feliksi baálẹ̀ ọlọ́lá jùlọ,
àlàáfíà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.