Ìṣe àwọn Aposteli 2:26
Acts 2:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí.
Acts 2:26 in English
Acts 2:26 · Berean Standard Bible
Therefore my heart is glad and my tongue rejoices; my body also will dwell in hope,
Context
24Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú, nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dìímú. 25Dafidi tí wí nípa tirẹ̀ pé:
“ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo níwájú mí,
nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi,
a kì ó ṣí mi ní ipò. 26Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀,
pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí. 27Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà òkú,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́. 28Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè,
ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.