Native Bible

Acts 2:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi tí wí nípa tirẹ̀ pé: “ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo níwájú mí, nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi, a kì ó ṣí mi ní ipò.

Acts 2:25 in English

Acts 2:25 · Berean Standard Bible

David says about Him: ‘I saw * the Lord always before me; because He is at my right hand, I will not be shaken.

Context

23Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, tí a sì pa á pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú, a kàn mọ́ àgbélébùú. 24Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, gbà á kúrò nínú ìrora ikú, nítorí tí kò ṣe é ṣe fún ikú láti dìímú. 25Dafidi tí wí nípa tirẹ̀ pé: “ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo níwájú mí, nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi, a kì ó ṣí mi ní ipò. 26Nítorí náà inú mi dùn, ahọ́n mi sì yọ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú ara mi yóò sì sinmi ní ìrètí. 27Nítorí tí ìwọ kí yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ni isà òkú, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.