Ìṣe àwọn Aposteli 13:47
Acts 13:47 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé: “ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ”
Acts 13:47 in English
Acts 13:47 · Berean Standard Bible
For this is what the Lord has commanded us: ‘I have made you a light for the Gentiles, to bring salvation to the ends of the earth.’*”
Context
45Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Paulu ń sọ. 46Paulu àti Barnaba sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà. 47Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé:
“ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà,
kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ” 48Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́. 49A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbègbè náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.