Native Bible

Acts 13:48 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́.

Acts 13:48 in English

Acts 13:48 · Berean Standard Bible

When the Gentiles heard this, they rejoiced and glorified the word of the Lord, and all who were appointed for eternal life believed.

Context

46Paulu àti Barnaba sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà. 47Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé: “ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ” 48Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́. 49A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbègbè náà. 50Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Paulu àti Barnaba, wọ́n sì le wọn kúrò ni agbègbè wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.