Native Bible

2 Samuel 3:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọba sì sọkún lórí Abneri, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ Abneri ó yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè?

2 Samuel 3:33 in English

2 Samuel 3:33 · Berean Standard Bible

And the king sang this lament for Abner: “Should Abner die the death of a fool?

Context

31Dafidi sì wí fún Joabu àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yin sì sọkún níwájú Abneri.” Dafidi ọba tìkára rẹ̀ sì tẹ̀lé pósí rẹ̀. 32Wọ́n sì sin Abneri ní Hebroni, ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sọkún ní ibojì Abneri; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sọkún. 33Ọba sì sọkún lórí Abneri, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ Abneri ó yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè? 34A kò sá à dè ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀. 35Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dafidi ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dafidi sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ oúnjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí oòrùn yóò fi wọ̀!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.