2 Samuẹli 3:32
2 Samuel 3:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì sin Abneri ní Hebroni, ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sọkún ní ibojì Abneri; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sọkún.
2 Samuel 3:32 in English
2 Samuel 3:32 · Berean Standard Bible
When they buried Abner in Hebron, the king wept aloud at Abner’s tomb, and all the people wept.
Context
30(Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì pa Abneri, nítorí pé òun ti pa Asaheli arákùnrin wọn ní Gibeoni ní ogun.) 31Dafidi sì wí fún Joabu àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yin sì sọkún níwájú Abneri.” Dafidi ọba tìkára rẹ̀ sì tẹ̀lé pósí rẹ̀. 32Wọ́n sì sin Abneri ní Hebroni, ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sọkún ní ibojì Abneri; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sọkún. 33Ọba sì sọkún lórí Abneri, ó sì wí pé,
“Ǹjẹ́ Abneri ó yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè? 34A kò sá à dè ọ́ lọ́wọ́,
bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà.
Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.”
Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.