Native Bible

2 Samuel 22:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, Olúwa; Olúwa yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.

2 Samuel 22:29 in English

2 Samuel 22:29 · Berean Standard Bible

For You, O LORD, are my lamp; the LORD lights up my darkness.

Context

27Fún onínú funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun; àti fún ẹni wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́. 28Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà; ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀. 29Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, Olúwa; Olúwa yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀. 30Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárín ogun kọjá; nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan. 31“Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀; ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti dánwò. Òun sì ni asà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.