Native Bible

2 Samuel 17:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọdékùnrin kan rí wọn, ó sì wí fún Absalomu, ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì sì yára lọ kúrò, wọ́n sì wá sí ilé ọkùnrin kan ní Bahurimu, ẹni tí ó ní kànga kan ní ọgbà rẹ̀, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ sí ibẹ̀.

2 Samuel 17:18 in English

2 Samuel 17:18 · Berean Standard Bible

But a young man did see them and told Absalom. So the two left quickly and came to the house of a man in Bahurim. He had a well in his courtyard, and they climbed down into it.

Context

16Nítorí náà yára ránṣẹ́ nísinsin yìí kí o sì sọ fún Dafidi pé, ‘Má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ijù náà lálẹ́ yìí, ṣùgbọ́n yára rékọjá kí a má bá a gbé ọba mì, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.’ ” 17Jonatani àti Ahimasi sì dúró ní En-Rogeli ọ̀dọ́mọdébìnrin kan sì lọ, ó sì sọ fún wọn, wọ́n sì lọ wọ́n sọ fún Dafidi ọba nítorí pé kí a má bá à rí wọn pé wọ́n wọ ìlú. 18Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọdékùnrin kan rí wọn, ó sì wí fún Absalomu, ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì sì yára lọ kúrò, wọ́n sì wá sí ilé ọkùnrin kan ní Bahurimu, ẹni tí ó ní kànga kan ní ọgbà rẹ̀, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ sí ibẹ̀. 19Obìnrin rẹ̀ sì mú nǹkan ó fi bo kànga náà, ó sì sá àgbàdo sórí rẹ̀, a kò sì mọ̀. 20Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tọ obìnrin náà wá sí ilé náà, wọ́n sì béèrè pé, “Níbo ni Ahimasi àti Jonatani gbé wà?” Obìnrin náà sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gòkè rékọjá ìṣàn odò náà.” Wọ́n sì wá wọn kiri, wọn kò sì rí wọn, wọ́n sì yípadà sí Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.