2 Samuẹli 17:20
2 Samuel 17:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tọ obìnrin náà wá sí ilé náà, wọ́n sì béèrè pé, “Níbo ni Ahimasi àti Jonatani gbé wà?” Obìnrin náà sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gòkè rékọjá ìṣàn odò náà.” Wọ́n sì wá wọn kiri, wọn kò sì rí wọn, wọ́n sì yípadà sí Jerusalẹmu.
2 Samuel 17:20 in English
2 Samuel 17:20 · Berean Standard Bible
When Absalom’s servants came to the woman at the house, they asked, “Where are Ahimaaz and Jonathan?” “They have crossed over the brook,” she replied. The men searched but did not find them, so they returned to Jerusalem.
Context
18Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọdékùnrin kan rí wọn, ó sì wí fún Absalomu, ṣùgbọ́n àwọn méjèèjì sì yára lọ kúrò, wọ́n sì wá sí ilé ọkùnrin kan ní Bahurimu, ẹni tí ó ní kànga kan ní ọgbà rẹ̀, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ sí ibẹ̀. 19Obìnrin rẹ̀ sì mú nǹkan ó fi bo kànga náà, ó sì sá àgbàdo sórí rẹ̀, a kò sì mọ̀. 20Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tọ obìnrin náà wá sí ilé náà, wọ́n sì béèrè pé, “Níbo ni Ahimasi àti Jonatani gbé wà?”
Obìnrin náà sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gòkè rékọjá ìṣàn odò náà.” Wọ́n sì wá wọn kiri, wọn kò sì rí wọn, wọ́n sì yípadà sí Jerusalẹmu. 21Ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti lọ tán, àwọn ọkùnrin náà sì jáde kúrò nínú kànga, wọ́n sì lọ wọ́n sì rò fún Dafidi ọba. Wọ́n sọ fún Dafidi pé, “Dìde kí o sì gòkè odò kánkán, nítorí pé báyìí ni Ahitofeli gbìmọ̀ sí ọ.” 22Dafidi sì dìde, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì gòkè odò Jordani: kí ilẹ̀ tó mọ́, ènìyàn kò kù tí kò gòkè odò Jordani.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.