2 Samuẹli 1:19
2 Samuel 1:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ògo rẹ, Israẹli ni a pa ní òkè gíga rẹ. Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú!
2 Samuel 1:19 in English
2 Samuel 1:19 · Berean Standard Bible
“Your glory, O Israel, lies slain on your heights. How the mighty have fallen!
Context
17Dafidi sì fi orin ọ̀fọ̀ yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Saulu àti lórí Jonatani ọmọ rẹ̀, 18Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Juda ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jaṣari): 19“Ògo rẹ, Israẹli ni a pa ní òkè gíga rẹ.
Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú! 20“Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gati,
ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Aṣkeloni,
kí àwọn ọmọbìnrin Filistini má bá à yọ̀,
kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má ba à dunnú. 21“Ẹ̀yin òkè Gilboa,
kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò,
tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá.
Nítorí ibẹ̀ ni asà alágbára ti ṣègbé,
asà Saulu, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.