2 Ọba 9:33
2 Kings 9:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jehu sọ wí pé, “Gbé e jù sílẹ̀!” Wọ́n sì jù ú sílẹ̀. Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn.
2 Kings 9:33 in English
2 Kings 9:33 · Berean Standard Bible
“Throw her down!” yelled Jehu. So they threw her down, and her blood splattered on the wall and on the horses as they trampled her underfoot.
Context
31Bí Jehu ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá ní àlàáfíà, Simri, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?” 32Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀. 33Jehu sọ wí pé, “Gbé e jù sílẹ̀!” Wọ́n sì jù ú sílẹ̀. Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn. 34Jehu wọ inú ilé lọ, ó jẹ, ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.” 35Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ láti lọ sin ín, wọn kò rí nǹkan kan àyàfi agbárí i rẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.