2 Ọba 9:34
2 Kings 9:34 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jehu wọ inú ilé lọ, ó jẹ, ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.”
2 Kings 9:34 in English
2 Kings 9:34 · Berean Standard Bible
Then Jehu went in and ate and drank. “Take care of this cursed woman,” he said, “and bury her, for she was the daughter of a king.”
Context
32Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀. 33Jehu sọ wí pé, “Gbé e jù sílẹ̀!” Wọ́n sì jù ú sílẹ̀. Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn. 34Jehu wọ inú ilé lọ, ó jẹ, ó sì mu. “Tọ́jú obìnrin yẹn tí a fi bú,” Ó wí, “Kí o sì sin ín, nítorí ọmọbìnrin ọba ni ó jẹ́.” 35Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n jáde lọ láti lọ sin ín, wọn kò rí nǹkan kan àyàfi agbárí i rẹ̀, ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì àti ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì. 36Wọ́n padà lọ sọ fún Jehu, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah ará Tiṣibi wí pé, ‘Ní orí oko Jesreeli ni àwọn ajá yóò ti jẹ ẹran-ara Jesebeli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.