2 Ọba 9:31
2 Kings 9:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí Jehu ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá ní àlàáfíà, Simri, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?”
2 Kings 9:31 in English
2 Kings 9:31 · Berean Standard Bible
And as Jehu entered the gate, she asked, “Have you come in peace, O Zimri, murderer of your master?”*
Context
29(Ní ọdún kọkànlá ti Joramu ọmọ Ahabu, Ahasiah ti di ọba Juda.) 30Nígbà náà Jehu lọ sí Jesreeli. Nígbà tí Jesebeli gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé. 31Bí Jehu ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá ní àlàáfíà, Simri, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?” 32Ó gbójú sókè láti wo fèrèsé, ó sì pè jáde, “Ta ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ mi? Ta ni?” Ìwẹ̀fà méjì tàbí mẹ́ta bojú wò ó nílẹ̀. 33Jehu sọ wí pé, “Gbé e jù sílẹ̀!” Wọ́n sì jù ú sílẹ̀. Díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì fọ́n sí ara ògiri àti àwọn ẹṣin bí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.