Native Bible

2 Kings 9:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

(Ní ọdún kọkànlá ti Joramu ọmọ Ahabu, Ahasiah ti di ọba Juda.)

2 Kings 9:29 in English

2 Kings 9:29 · Berean Standard Bible

(In the eleventh year of Joram son of Ahab, Ahaziah had become king over Judah.)

Context

27Nígbà tí Ahasiah ọba, Juda rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Beti-Haggani. Jehu sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n ṣá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Guri lẹ́bàá a Ibleamu, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Megido, ó sì kú síbẹ̀. 28Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, ó sì sin ín pẹ̀lú, baba a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi. 29(Ní ọdún kọkànlá ti Joramu ọmọ Ahabu, Ahasiah ti di ọba Juda.) 30Nígbà náà Jehu lọ sí Jesreeli. Nígbà tí Jesebeli gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé. 31Bí Jehu ti wọ ẹnu ìlẹ̀kùn, ó béèrè, “Ṣé ìwọ wá ní àlàáfíà, Simri, ìwọ olùpa ọ̀gá à rẹ?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.