2 Ọba 9:28
2 Kings 9:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, ó sì sin ín pẹ̀lú, baba a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi.
2 Kings 9:28 in English
2 Kings 9:28 · Berean Standard Bible
Then his servants carried him by chariot to Jerusalem and buried him with his fathers in his tomb in the City of David.
Context
26‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Naboti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni Olúwa wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa.” 27Nígbà tí Ahasiah ọba, Juda rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Beti-Haggani. Jehu sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n ṣá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Guri lẹ́bàá a Ibleamu, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Megido, ó sì kú síbẹ̀. 28Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, ó sì sin ín pẹ̀lú, baba a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi. 29(Ní ọdún kọkànlá ti Joramu ọmọ Ahabu, Ahasiah ti di ọba Juda.) 30Nígbà náà Jehu lọ sí Jesreeli. Nígbà tí Jesebeli gbọ́ nípa rẹ̀, ó kun ojú u rẹ̀, ó to irun rẹ̀, ó sì wò jáde láti ojú fèrèsé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.