2 Ọba 9:27
2 Kings 9:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Ahasiah ọba, Juda rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Beti-Haggani. Jehu sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n ṣá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Guri lẹ́bàá a Ibleamu, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Megido, ó sì kú síbẹ̀.
2 Kings 9:27 in English
2 Kings 9:27 · Berean Standard Bible
When King Ahaziah of Judah saw this, he fled up the road toward Beth-haggan. And Jehu pursued him, shouting, “Shoot him too!” So they shot Ahaziah in his chariot on the Ascent of Gur,* near Ibleam, and he fled to Megiddo and died there.
Context
25Jehu sọ fún Bidikari, balógun kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Gbé e sókè kí ó sì jù ú sí orí oko tí ó jẹ́ ti Naboti ará Jesreeli. Rántí bí èmi àti ìwọ ti ń gun kẹ̀kẹ́ papọ̀ lẹ́yìn Ahabu baba à rẹ nígbà tí Olúwa sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀, 26‘Ní àná, mo rí ẹ̀jẹ̀ Naboti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ni Olúwa wí.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ gbé e sókè, kí o sì jù ú sí orí ilẹ̀ oko náà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa.” 27Nígbà tí Ahasiah ọba, Juda rí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó sálọ sójú ọ̀nà sí Beti-Haggani. Jehu sì lépa rẹ̀, ó ń kígbe, “Pa á pẹ̀lú!” Wọ́n ṣá a ní ọgbẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹ rẹ̀ ní ọ̀nà lọ sí Guri lẹ́bàá a Ibleamu, ṣùgbọ́n ó sálọ sí Megido, ó sì kú síbẹ̀. 28Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbé e pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, ó sì sin ín pẹ̀lú, baba a rẹ̀ nínú ibojì rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Dafidi. 29(Ní ọdún kọkànlá ti Joramu ọmọ Ahabu, Ahasiah ti di ọba Juda.)
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.