2 Ọba 25:5
2 Kings 25:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará Kaldea sì lépa ọba, wọ́n sì lé e bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká,
2 Kings 25:5 in English
2 Kings 25:5 · Berean Standard Bible
but the army of the Chaldeans pursued the king and overtook him in the plains of Jericho, and all his army was separated from him.
Context
3Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsànán oṣù kẹrin, ìyàn tí mú ní ìlú tí ó jẹ́ wí pé kò sí oúnjẹ fún àwọn ènìyàn láti jẹ. 4Nígbà náà odi ìlú náà sì fọ́nká, gbogbo àwọn ọmọ-ogun sálọ ní òru láti ẹnu-ọ̀nà bodè láàrín ògiri méjì ní ẹgbẹ́ ọgbà ọba, àwọn ará Babeli wọ́n sì yí ìlú náà ká. Wọ́n sálọ sí ìkọjá Arabah. 5Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará Kaldea sì lépa ọba, wọ́n sì lé e bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká, 6wọ́n sì mú un.
Wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli ní Ribla, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀. 7Wọ́n sì pa ọmọ Sedekiah níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Babeli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.