2 Ọba 25:3
2 Kings 25:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsànán oṣù kẹrin, ìyàn tí mú ní ìlú tí ó jẹ́ wí pé kò sí oúnjẹ fún àwọn ènìyàn láti jẹ.
2 Kings 25:3 in English
2 Kings 25:3 · Berean Standard Bible
By the ninth day of the fourth month,* the famine in the city was so severe that the people of the land had no food.
Context
1Nígbà tí ó di ọdún kẹsànán ìjọba Sedekiah. Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹwàá, Nebukadnessari ọba Babeli yan lọ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀. Ó sì pàgọ́ sí ìta ìlú ó sì mu àwọn iṣẹ́ ìdọ̀tí fi yí gbogbo rẹ̀ ká. 2Ìlú náà sì wà ní ìhámọ́ lábẹ́ ìgbóguntì títí di ọdún kọkànlá ti ọba Sedekiah. 3Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹsànán oṣù kẹrin, ìyàn tí mú ní ìlú tí ó jẹ́ wí pé kò sí oúnjẹ fún àwọn ènìyàn láti jẹ. 4Nígbà náà odi ìlú náà sì fọ́nká, gbogbo àwọn ọmọ-ogun sálọ ní òru láti ẹnu-ọ̀nà bodè láàrín ògiri méjì ní ẹgbẹ́ ọgbà ọba, àwọn ará Babeli wọ́n sì yí ìlú náà ká. Wọ́n sálọ sí ìkọjá Arabah. 5Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará Kaldea sì lépa ọba, wọ́n sì lé e bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.