Native Bible

2 Kings 25:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì pa ọmọ Sedekiah níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Babeli.

2 Kings 25:7 in English

2 Kings 25:7 · Berean Standard Bible

And they slaughtered the sons of Zedekiah before his eyes. Then they put out his eyes, bound him with bronze shackles, and took him to Babylon.

Context

5Ṣùgbọ́n ogun àwọn ará Kaldea sì lépa ọba, wọ́n sì lé e bá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jeriko. Gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sì yà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì túká, 6wọ́n sì mú un. Wọ́n sì mú lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli ní Ribla, níbi tí à ti ṣe ìdájọ́ lórí rẹ̀. 7Wọ́n sì pa ọmọ Sedekiah níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Babeli. 8Ní ọjọ́ keje ní oṣù karùn-ún, ní ọdún kọkàndínlógún ti Nebukadnessari ọba Babeli, Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu; 9ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jerusalẹmu àti gbogbo ilé ńlá ńlá ni ó dáná sun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.